Not money or fame by Tom Sharp

It isn’t money; it isn’t fame or your attention, but poetry in the line, in the life, a lifeline. I am hooked by its jazz-like ease, its difficulty, a contradiction that gives me eyes and ears. I see the blind, who can see only money, and hear the deaf, who can sing for only fame. I learned if I try, then I can forget to try. I learned I can sing without learning the notes. No one pays you to look up and see the sky; no one loves you because you can sleep in peace. People used to live without earning money, but living without love, without poetry, is like death.

Máfipáwówó by XYX

Ẹ métí bora kẹ́ gbóhun tí mo fẹ́ wí orin ewì ń gbé mi nínú Ibi mo sọ̀rọ̀ dé ni ngó fàbọ̀ sí Orin ọgbọ́n ṣẹ́kù nínú mi Orin olówó lorin tó yó sí mi lẛnu Kò sí gbàrọgùdù mọ́, orin olówó ló kù nílẹ̀ Mo ní b’ọ́lọ́lá ayé ti lọ́lá tó Ọlọ́lá ò le sùn kó dijú tán Owó ni wọ́n tún fi ojojúmọ́ lé pa kiri Àjáàjo ò sì jẹ́ kí wọ́n rí ìhà méjééjì sùn Wọn ò ráyè sùn lálẹ́ Wọn ò ráyè orun lójú mọmọ Bẹ́ẹ̀ni àsùnfalala àsùnjátọ́ lọmọ tálákà ń sùn Àá ti gbọ́ pé èèyàn lówó tán irú wọn ò tún kófà orun Ka rójú tán ka tún mọ́ọ wákú kiri Ká ti rírọ̀rùn tán, ká mọ́ọ wá wàhálà Nítòótọ́ ni mo gbọ́ pé olúṣekún ìná kìí tánwó Owó táa ṣiṣẹ́ fún ní lọ́ra lọ́wọ́ ẛni Ẹ̀mí owó ò lè gùn fẹ́ni tó bá ń sùn sílẹ̀ Ṣugbọn béyàn bá lówó ó yẛ kó tún lè nísinmi Èwo ni ká wówówówó ká wá dẛrú owó Kọ́mọ ẹ̀dá ó ma rọ́jú kẹ̀wù ìdàmú bọra rẹ̀ lọ́rùn Ká sáré lọ ní kùtùkùtù ìdájí ká wọlé lọ́gànjọ́ lóru Kójú ó tó mọ́ ká ti tún lọ Ká máa ṣe kìtàkìtà ní gbogbo àkókò Ẹ bá mi wí fólówó Kí wọn ó yé tọwọ́ bọ ikú lójú Kí ọmọ èyàn ó sinmi díẹ̀ kí ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ ló tọ̀nà Ẹ bá mi sọ fún ọlọ́rọ̀ kó fúnra rẹ̀ láàyè ìsinmi Kó le hu irun funfun lórí kó tó lọ sálákeji Èyàn tí ò bá sinmi ní kú láyì tásìkò Ìhòhò pátá la kúkú rìn wáyé, ọwọ́ lọmọ ẹ̀dá ń sán r’ọ̀run Kóní kálùlù ó yé pára rẹ̀ láyà